Jeremiah 49:23-27

Àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Damasku

23Nípa Damasku,

“Inú Hamati àti Arpadi bàjẹ́ nítorí wọ́n gbọ́ ìròyìn búburú, ìjayà dé bá wọn,
wọ́n sì dààmú bí omi Òkun.
24Damasku di aláìlera, ó pẹ̀yìndà
láti sálọ, ìwárìrì sì dé bá a,
ìbẹ̀rù àti ìrora dìímú, ìrora
bí ti obìnrin tí ó wà ní ipò ìrọbí.
25Kí ló dé tí ìlú olókìkí di ohun ìkọ̀sílẹ̀;
ìlú tí mo dunnú sí.
26Lóòtítọ́, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ
yóò ṣubú lójú pópó, gbogbo
àwọn ọmọ-ogun rẹ yóò pa
ẹnu mọ́ ní ọjọ́ náà,”
Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
27“Èmi yóò fi iná sí odi Damasku,
yóò sì jó gbọ̀ngàn Beni-Hadadi run.”
Copyright information for YorBMYO